Eyin temi,
O dabi wipe pupo ninu wa ti gbagbe pe ko si oun ti a mu wa ile aye, ko de si oun ti a de ma mu pada lo.
Ayafi ise ti a ba se ati iwa ti a hu nigbati a wa ni ori iyepe. Ki lo wa de ti a wa fi nwa aye mo aya bi eni ti o le ko dukia dani lo si orun?
Ati ko dukia jo de wa je opo eniyan logun debi wipe won o ko lati pa omo won abi iya won ti won ba ti le di olowo.
Kilode!!!!!!!! Oro yi o ko omode, ko ko agbalagba. Oko ti n pa Iyawo, beni iyawo n pa oko nitori owo. Awon aji Omo gbe wa kun igboro.
E dakun, e je ka se suuru. E je ka ranti ojo ati sun wa. E je ka ranti ojo ti o ma ku wa ku iwa wa. Ka ma tori owo ba eyin wa je.
Gbogbo wa la mo wipe ita le. Ko si owo lode. Ebi n pa opolopo eniyan. E ma wa je ko je a ma wa fi ara ni omo lakeji wa nitori wipe a fe ni owo.
E je ka ranti awon omo wa. Ti o ba pa omolomo lekun lati fi to awon omo ti e, esan nbo ooo. Gbogbo waduwadu yi o da nkankan. Aye la ba, aye la ma fi sile si. E se jeje nitori Olorun Oba.
Mo ki gbogbo yin tayo tayo. Mo ki yin teye teye. E seun. Mo dupe gan fun asiko ti e fisile lati ka aroye mi. E jowo e je kin gbo ero okan yin lori oro yi ni aiye towa ni isale. E dakun e fi ife han mi, Eba mi pin aroye yin fun awon ore yin. Esi ma gbagbe lati darapo mowa ni ibiyi. Emi ni ti yin ni tooto,
Ruka
Check Natural Skincare Products here. Homemade Recipes here.
Emi ni tiyin,
Ruka