Eyanmi,
Ipo ki ipo ti o baa wa, iwo sa ma ranti wipe….
Bi won gun iyan ninu ewe, ti won se obe ninu epo epa, eni mayo a kuku yo.
Oro nla ni ooo. Ki Eledumare ka wa mo awon ti o ma yo ni o. Amin Nola. Amin nla.
Bi oro yi se ye emi si re – Bi o ti lehun ki nkan kere mo, awon eniyan kan wa ti won a si ri nkankan se pelu e. Ona le di, gbogbo nkan le dojuru, ki gbogbo e le kokoko bi oju eja, ona a si wa fun awon eniyan kan.
Ki se mimo se awon eniyan won yi, biko se anu Oluwa ati itiraka won. Bi Oba oke ba sa anu wa awa no lati fi igbiyanju tele. Nitori idi igbiyanju wa ni anu yi a ti sise. Abi?
Igba mi wa ti a fe da owo le nkan sugbon a fe ki ani ororisi nko lowo ki a to lese, eyi a maa je ki ireti wa pe. Gbogbo wa la de mo wipe ireti pipe maa nse okan ni are. Boya ti baa ya oro yi lo aseyori e atete de.
Dakun, ma duro di igba ti gbogbo nkan ba gun rege ki o to bere si se ohun to wa ni okan re lati mu aiye re da. Beere ni isisinyi, lo awon ohun ti owa ni ikawo e. Gba wipe omo to ba shipa ni iya re ma gbe.
To, mo wire tabi mi o wire? E jowo eba mi fi esi si isale. Ona gbogbo wa onidi ooo.
Mo ki gbogbo yin tayo tayo. Mo ki yin teye teye. E seun. Mo dupe gan fun asiko ti e fisile lati ka aroye mi. E jowo e je kin gbo ero okan yin lori oro yi ni aiye towa ni isale. E dakun e fi ife han mi, Eba mi pin aroye yin fun awon ore yin. Esi ma gbagbe lati darapo mowa ni ibiyi.
Emi ni ti re ni tooto,
Ruka
Check Natural Skincare Products here. Homemade Recipes here.