0 0
Read Time:2 Minute, 3 Second

Eyanmi,

Awa Yoruba ni – Eni ma da aso fun ni, ti orun re ni kawo. Abi iwo oti gbo oro yi ri ni?

Oda, je ki hun se alaye oro yi fun e. Ti o ba fe ki nkan ti o hun se abi ti o fe se ni aseyori, owo tani oti ma lo bere imoran? Se lowo eni ti ko se iru re ri ni, abi lowo eni to ti se ri lo ma lo?

Iwo no ati ri wipe idi ti opolopo awa eniyan se ma nsise niyi. Igba mi ati itori wipe eniyan je agbalagba gbogbo nkan ti iru eni be baso la ma tele. Asise nla gba ni, opolopo ni oro aye won ti daru nitori eyi.

Ki a bowo fun agbalagba ya to si ki a tele gbogbo nkan ti won ba wi fun wa lalai gbeyewo. Elomiran dagba lasan ni, ebun ti won fi ma yanju oro eledumare ko fi fun won. Oye yato si ojo ori.

La oju e, ki o wo eni ti o fe fun e ni imoran. Bawo ni oro ti e se wa si. Bi o ba fe fi ejo oko tabi iyawo re sun eniyan yi, ro wipe bawo ni ile eni yi se wa? Bi o ba je awon omo re ni won nba e ninu je, ta lo fe lo ro ejo fun? Se awon omo eniyan yi yan, won yanju?

La oju e dada ki o maa ba ba ile aiye ara re je. So ara fun gbigba imoran lowo taja teran. Iwo na joko ki o pe aro ati odofin inu re, ro arojinle. Ke pe eleda re, Oba awi mayehun a ba e gbe oro e laisi abosi.

Dakun ma si mi gbo oooo, ki se gbogbo eniyan to nfun ni ni imoran ni won nse ibi ooo. Emi kan ni ki o laju re dada, ki o si ranti wipe- Eni ma da aso fun ni, ti orun re ni kawo.

Mo ki gbogbo yin tayo tayo. Mo ki yin teye teye. E seun. Mo dupe gan fun asiko ti e fisile lati ka aroye mi. E jowo e je kin gbo ero okan yin lori oro yi ni aiye towa ni isale. E dakun e fi ife han mi, Eba mi pin aroye yin fun awon ore yin. Esi ma gbagbe lati darapo mowa ni ibiyi.

Emi ni ti re ni tooto,

Ruka

Check Natural Skincare Products here. Homemade Recipes here.

About Post Author

Ruka

My name is Ruka. Born and bred in Nigeria. Now living in Ireland. I am a Woman, Feminist, Wife, Mother, Muslim, Black, and African. I am an Entrepreneur who also works in Finance Administration. I am a Fibromyalgia & Chronic Pain Warrior. I love writing and hope to make a name for myself doing it.
Happy
Happy
0 %
Sad
Sad
0 %
Excited
Excited
0 %
Sleepy
Sleepy
0 %
Angry
Angry
0 %
Surprise
Surprise
0 %

Average Rating

5 Star
0%
4 Star
0%
3 Star
0%
2 Star
0%
1 Star
0%

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *