0 0
Read Time:1 Minute, 34 Second

Eyanmi,

Mo fi Olorun to da gbogbo wa be e, jowo ibi ti o baa nlo ni ki o ko oju mo.

Opolopo awon eniyan lo wa ni igbooro to je wipe won o ni nkan se, won o de ni je ki eni ti o fe se nkan se.

Won a wa bi eniyan gidi, wa lero pe won mo nkan ti won nso, agbaa ofifo lasan ni won. Ore mi lo so ara re.

Opolopo ninu awon eyan yi paapaa ko mo wipe awon o mo nkankan. Ti o ba je ki won da irin Ajo e ru, iwo de lomo.

Yoruba ni eni o mona to hun da padepade ohun oju e hun wa lo ma ri!

Itumo ki eniyan ma beere ona lowo eniti ko lo ibi ti eyan nlo gan ke?

Ni igbagbo ninu ara re. Ranti wipe iwo lo mo ibi ti ohun lo. Igbesi aye re de ni. Kilo wade ti o fi je wipe elomi lo ma wa ma daari bo se ma rin irin ajo aiye re?

Igba mi ibi ti a nlo ki jinna rara, ibi ti a hun yasi lopo gan. Idi ti irin ajo mi se ma hun pe niyen. Amo tio ba ko oju mo ona e, ayaba onidi e lowo.

E je ki a ko oju mo ona wa, ki a ye wo ago alaago sise. Eledumare a la ona fun gbogbo wa ooo.

Dakun gbaju mo ona ti e!

Mo dupe gan fun asiko ti e fisile lati ka aroye mi. E jowo e je kin gbo ero okan yin lori oro yi ni aiye towa ni isale. E dakun e fi ife han mi Eba mi pin aroye yin fun awon ore yin. Esi ma gbagbe lati darapo mowa ni ibiyi.

Emi ni ti e ni tooto,

Ruka

Check Natural Skincare Products here. Homemade Recipes here.

About Post Author

Ruka

My name is Ruka. Born and bred in Nigeria. Now living in Ireland. I am a Woman, Feminist, Wife, Mother, Muslim, Black, and African. I am an Entrepreneur who also works in Finance Administration. I am a Fibromyalgia & Chronic Pain Warrior. I love writing and hope to make a name for myself doing it.
Happy
Happy
0 %
Sad
Sad
0 %
Excited
Excited
0 %
Sleepy
Sleepy
0 %
Angry
Angry
0 %
Surprise
Surprise
0 %

Average Rating

5 Star
0%
4 Star
0%
3 Star
0%
2 Star
0%
1 Star
0%

2 thoughts on “Ko Oju Mo Ona Re!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *